Iseyin orò ọmọ ebedi mọkọ

Iseyin orò ọmọ ebedi mọkọ Iseyin township page and direction of every locations

29/04/2024

New Iseyin Anthem 🎶🔔

NEW ISEYIN ANTHEM 🔔🎶 Ìséyìn sá n'ìlú mi t'a bí mi síN ò mà l'ókè méjì l'ẹ́hìn ọ̀runB'ẹ bá n w'ásọ òfì t'ó sunwọnÌlú Ìséy...
29/04/2024

NEW ISEYIN ANTHEM 🔔🎶

Ìséyìn sá n'ìlú mi t'a bí mi sí
N ò mà l'ókè méjì l'ẹ́hìn ọ̀run
B'ẹ bá n w'ásọ òfì t'ó sunwọn
Ìlú Ìséyìn orò ni k'ẹ́ẹ wá

T'olórí t'ẹlẹ́mù, ẹ jáde wá
K'a gb'Ẹ́bẹdíí s'ókè, k' ó lè ga
Kò s'óhun tó yẹ k'á ṣe fún 'Sẹyìn
Ju k'á gbe dé'bi gíga mà l'a fẹ́

Aráa'wájú, ẹ gbe n'íwájú
Èrò tó n bẹ l'ẹ́hìn, ẹ má sùn lọ
Àjèjé ọwọ́ t'ẹ rí yan ò
Kò leè gb'ẹ́rù dé'bi à n fee.

Ìdàgbàs'ókè yí jẹ mí l'ógún
N ò mà ní f'ọwọ́ si, k'ó bàjẹ́
Mà á s'apá mi dé 'bi t'ó yẹ ò
K'Ìsẹ́yìn ó lè dé'lẹ̀ ìlérí

Lead: Ẹ má jẹ́ ó bàjẹ́ ọmọ Asẹ́yìn
Chrs: Kò mà le è bàjẹ́ ọmọ Asẹ́yìn
Lead: Orírun wa sá n'ilẹ̀ yi, ẹ gbe s'ókè
* Ìpìlẹ̀ wa rèé, ẹ gbe l'árugẹ
* Ẹbẹdí n'ilé mi o, n'íbi t'a bí mi

Ìséyìn l'a gbé ti wò mí, má gbe l'árugẹ
* N ó s'apá mi ò, k'á jọ gbe d'ókè
* K'á gb'Ẹbẹdí ga ò, ojúṣe wa sá ni
* Kò ní t'ọwọ́ mi bàjẹ́, ma ya bá wọn gbe
* Ẹ jọ̀wọ́ ẹ májẹ́ ó bàjẹ́ ọmọ Asẹ́yìn
* Kinní yìí d'ọwọ́ Àṣebí
Chorus: Àṣebí l'orò, níbẹ̀ l'ẹ bí waaaa.

25/08/2023

Welcome to iseyin home page 🏡

Address

Iseyin
202101

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Iseyin orò ọmọ ebedi mọkọ posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Share